31 Àwọn Júù sì tún he òkúta, láti sọ lù ú.
32 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”
33 Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ ṣe Ọlọ́run.”
34 Jésù dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’?
35 Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé-mímọ́ jẹ́,
36 Ẹ̀yin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sí mímọ́, tí ó sì rán sí ayé pé: Ìwọ ń sọ̀rọ̀ òdì, nítorí tí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’
37 Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.