36 Ẹ̀yin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sí mímọ́, tí ó sì rán sí ayé pé: Ìwọ ń sọ̀rọ̀ òdì, nítorí tí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’
37 Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.
38 Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin baà lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.”
39 Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.
40 Ó sì tún kọjá lọ sí apá kéjì Jodánì sí ibi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń bamítísì; níbẹ̀ ni ó sì jókòó.
41 Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Jòhánù kò ṣe iṣẹ́ àmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Jòhánù sọ nípa ti ọkùnrin yìí.”
42 Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbàágbọ́.