6 Òwe yìí ni Jésù pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí jẹ́ tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.
7 Nítorí náà Jésù tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn.
8 Olè àti ọlọ́sà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ ti wọn.
9 Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, Òun ni a ó gbà là, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko.
10 Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.
11 “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.
12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkokò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri.