14 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú,
15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
16 “Nítorí náà Tómásì, ẹni tí à ń pè ní Dídímù, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”
17 Nítorí náà nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ijọ́ mẹ́rin ná,
18 Ǹjẹ́ Bétanì sún mọ́ Jérúsálẹ́mù tó ibùsọ Mẹ́ẹ̀dógún:
19 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Màta àti Màríà láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.
20 Nítorí náà, nígbà tí Màta gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé.