33 Nígbà tí Jésù rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́.
34 Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”
35 Jésù sọkún.
36 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
37 Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣeé kí ọkùnrin yìí má kú bí?”
38 Nígbà náà ni Jésù tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.
39 Jésù wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”Màtá, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ijọ́ kẹrin tí ó tí kú.”