47 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí pe ìgbìmọ̀ jọ, wọ́n sì wí pé,“Kínni àwa ń ṣe? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.
48 Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Rómù yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”
49 Ṣùgbọ́n Káyáfà, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!
50 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó sàǹfàní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má baà ṣègbé.”
51 Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà:
52 Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà:
53 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.