9 Jésù dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.
10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”
11 Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lásárù ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”
12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá se pé ó sùn, yóò sàn.”
13 Ṣùgbọ́n Jésù ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.
14 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú,
15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.