9 Olórí àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Olórí àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apákan,
10 Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà níí wọ́n a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinyìí.”
11 Èyí jẹ́ àkọ́se iṣẹ́ àmì rẹ̀, tí Jésù ṣe ní Kánà ti Gálílì. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.
12 Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kápérnámù, Òun àti Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.
13 Àjọ-ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù,
14 Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàsípàrọ̀ owó ní tẹ́ḿpìlì wọ́n jòko:
15 Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó sì bi tábìlì wọn ṣubú.