16 Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Símónì ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi bí?”Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”
17 Ó wí fún un nígbà kẹ́ta pé, “Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ràn mi bí?”Inú Pétérù sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹ́ta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Jésù wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”
18 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ ó na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.
19 (Ó wí èyí, ó fi ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo.) Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
20 Pétérù sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó fararọ̀ súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹ̀ni tí ó fi ọ́ hàn?”
21 Nígbà tí Pétérù rí i, ó wí fún Jésù pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”
22 Jésù wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”