46 Bẹ́ẹ̀ ni Jésù tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kápérnámù.
47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ti Jùdéà wá sí Gálílì, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.
48 Nígbà náà ni Jésù wí fún u pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”
49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”
50 Jésù wí fún un pé, “Má a bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”
51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàde rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè.
52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí kéje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”