11 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”
12 Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”
13 Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jésù ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.
14 Lẹ́yìn náà, Jésù rí i ní tẹ́ḿpìlì ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má se dẹ́sẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”
15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jésù ni ẹni tí ó mú òun láradá.
16 Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí Ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.
17 Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”