13 Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jésù ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.
14 Lẹ́yìn náà, Jésù rí i ní tẹ́ḿpìlì ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má se dẹ́sẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”
15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jésù ni ẹni tí ó mú òun láradá.
16 Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí Ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.
17 Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”
18 Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.
19 Nígbà náà ni Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò se ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú.