64 Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́,” nítorí Jésù mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn.
65 Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.”
66 Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì báa rìn mọ́.
67 Nítorí náà Jésù wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?”
68 Nígbà náà ni Símónì Pétérù dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.
69 Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
70 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya Èṣù?”