8 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù wí fún un pé,
9 “Ọmọdékùnrin kan ńbẹ níhínyìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùnún àti ẹja kékèké méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”
10 Jésù sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Kóríkó púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye.
11 Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọn bí wọ́n ti ń fẹ́.
12 Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.”
13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.
14 Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́-àmì tí Jésù ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.”