21 Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ àmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín.
22 Síbẹ̀, nítorí pé Mósè fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ mósè bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi.
23 Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mósè, ẹ ha ti ṣe ń bínú sími, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ṣáṣá ní ọjọ́ ìsinmi?
24 Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa se ìdájọ́ òdodo.”
25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jérúsálẹ́mù wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí?
26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nkankan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, Èyí ni Kírísítì náà?
27 Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kírísítì bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”