50 Nikodémù ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,
51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”
52 Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Gálílì bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Gálílì dìde.”
53 Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.