15 Nítorí náà àwọn Farisí pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsìì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.”
16 Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisí wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàárin wọn.
17 Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ wí nítorí rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?”Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.”
18 Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú.
19 Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?”
20 Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú:
21 Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni Òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnra rẹ̀.”