47 “Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa.
48 Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn.
49 Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì se wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn àpósítélì sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’
50 Kí a lè bèèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;
51 Láti ẹ̀jẹ̀ Ábélì wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sakaráyà, tí ó ṣègbé láàrin pẹpẹ àti tẹ́ḿpìlì: lóòótọ́ ni mo wí fún yín.
52 “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.”
53 Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀.