10 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rírí,“ ‘kí wọn má baà rí,àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’
11 “Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
12 Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni Èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.
13 Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sáà díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.
14 Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó.
15 Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.
16 “Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àketè; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀.