20 Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́,
21 Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí?
22 Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kóríra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹ́ḿpìlì ní olè bí?
23 Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin?
24 Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ, “Orúkọ Ọlọ́run sáà di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrin àwọn aláìkọlà nítorí yín,”
25 Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà.
26 Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí akọ nílà bí?