17 Omiri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá kúrò ní ìlú Gibetoni, wọ́n lọ dó ti ìlú Tirisa.
18 Nígbà tí Simiri rí i pé ọwọ́ ti tẹ ìlú náà, ó lọ sí ibi ààbò tí ó wà ninu ààfin, ó tiná bọ ààfin, ó sì kú sinu iná;
19 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, tí ó tọ ọ̀nà tí Jeroboamu tọ̀, ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá: tí ó mú kí àwọn ọmọ Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀.
20 Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
21 Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri.
22 Níkẹyìn, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Omiri ṣẹgun àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati. Tibini kú, Omiri sì jọba.
23 Ní ọdún kọkanlelọgbọn tí Asa, ọba Juda ti wà lórí oyè, ni Omiri gorí oyè ní Israẹli. Ó sì jọba fún ọdún mejila. Ìlú Tirisa ni ó gbé fún ọdún mẹfa àkọ́kọ́.