17 Lẹ́yìn èyí, ọmọ obinrin opó yìí ṣàìsàn. Àìsàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọmọ náà ṣàìsí.
18 Obinrin náà bá bi Elija pé, “Eniyan Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí? Ṣé o wá sọ́dọ̀ mi láti rán Ọlọrun létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati láti ṣe ikú pa ọmọ mi ni.”
19 Elija dáhùn pé, “Gbé ọmọ náà fún mi.” Ó bá gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e gun orí òkè ilé lọ sinu yàrá tí ó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀.
20 Ó képe OLUWA, ó ní, “OLUWA, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi jẹ́ kí irú ìdààmú yìí bá obinrin opó tí mò ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ yìí, tí o jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?”
21 Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.”
22 OLUWA dáhùn adura Elija, ẹ̀mí ọmọ náà sì tún pada sinu rẹ̀, ó sì sọjí.
23 Elija gbé ọmọ náà sọ̀kalẹ̀ pada sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó! Ọmọ rẹ ti sọjí.”