10 “Mo wà ní orí òkè fún odidi ogoji ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, OLUWA sì tún gbọ́ ohùn mi, ó gbà láti má pa yín run.
11 OLUWA wí fún mi pé, ‘Gbéra, kí o máa lọ láti ṣáájú àwọn eniyan náà, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún wọn pé n óo fún wọn.’
12 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, kò sí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fẹ́ kí ẹ ṣe, àfi pé kí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn yín ati ẹ̀mí yín,
13 kí ẹ sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀, tí mo paláṣẹ fun yín lónìí mọ́, fún ire ara yín.
14 Wò ó, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ni ọ̀run, ati ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;
15 sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé.
16 Nítorí náà, ẹ gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí ẹ má sì ṣe oríkunkun mọ́.