1 “Bí ẹ bá rí òkú eniyan tí wọ́n pa sinu igbó, lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ kò sì mọ ẹni tí ó pa á,
2 kí àwọn àgbààgbà ati àwọn adájọ́ yín jáde wá, kí wọ́n wọn ilẹ̀ láti ibi tí wọ́n pa ẹni náà sí títí dé gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká ibẹ̀.
3 Kí àwọn àgbààgbà ìlú tí ó bá súnmọ́ ibẹ̀ jùlọ wá ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì so àjàgà mọ́ lọ́rùn láti fi ṣiṣẹ́ rí,
4 kí wọ́n mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù náà lọ sí àfonífojì tí ó ní odò tí ń ṣàn, tí ẹnikẹ́ni kò gbin ohunkohun sí rí, kí wọ́n sì lọ́ ọ̀dọ́ mààlúù náà lọ́rùn pa níbẹ̀.
5 Kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, bá wọn lọ pẹlu; nítorí àwọn ni OLUWA Ọlọrun yín yàn láti máa ṣe alufaa ati láti máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA; ati pé àwọn ni OLUWA Ọlọrun yàn láti parí àríyànjiyàn ati ẹjọ́.
6 Kí gbogbo àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ní ìlú náà wẹ ọwọ́ wọn sórí mààlúù tí wọ́n ti lọ́ lọ́rùn pa yìí.
7 Kí wọ́n wí pé, ‘A kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ẹni tí ó pa á.
8 OLUWA, dáríjì Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí o ti rà pada, má sì ṣe jẹ àwọn eniyan Israẹli níyà nítorí ikú aláìṣẹ̀ yìí. Ṣugbọn dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà jì wọ́n.’
9 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ ara yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀, bí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA.
10 “Nígbà tí ẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì kó wọn lẹ́rú;
11 tí ẹ bá rí arẹwà obinrin kan láàrin àwọn ẹrú náà tí ó wù yín láti fi ṣe aya fún ara yín.
12 Ẹ mú un wá sí ilẹ̀ yín ẹ fá irun orí rẹ̀, kí ẹ sì gé èékánná ọwọ́ rẹ̀.
13 Ẹ bọ́ aṣọ ẹrú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó wà ní ilẹ̀ yín, kí ó sì máa ṣọ̀fọ̀ baba ati ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan. Lẹ́yìn náà ẹ lè wọlé tọ̀ ọ́, kí ẹ sì di tọkọtaya.
14 Lẹ́yìn náà, tí kò bá wù yín mọ́ ẹ níláti fún un láyè kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá wù ú, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ tà á bí ẹrú, ẹ kò sì gbọdọ̀ lò ó ní ìlò ẹrú, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bá a lòpọ̀ rí.
15 “Bí ẹnìkan bá ní iyawo meji, tí ó fẹ́ràn ọ̀kan, tí kò sì fẹ́ràn ekeji, tí àwọn mejeeji bímọ fún un, tí ó bá jẹ́ pé iyawo tí kò fẹ́ràn ni ó bí àkọ́bí ọmọkunrin rẹ̀ fún un,
16 ní ọjọ́ tí yóo bá ṣe ètò bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóo ṣe pín ogún rẹ̀, kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, kí ó pín ogún fún ọmọ ẹni tí ó fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, kí ó sì ṣe ọmọ ẹni tí kò fẹ́ràn bí ẹni pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí rẹ̀.
17 Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí.
18 “Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́,
19 kí baba ati ìyá rẹ̀ mú un wá siwaju àwọn àgbààgbà ìlú náà, ní ẹnu bodè ìlú tí ó ń gbé,
20 kí wọ́n wí fún àwọn àgbààgbà ìlú náà pé, ‘Ọmọ wa yìí ya olóríkunkun ati aláìgbọràn, kì í gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Oníjẹkújẹ ati onímukúmu sì ni.’
21 Lẹ́yìn náà kí àwọn ọkunrin ìlú sọ ọ́ ní òkúta pa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ ibi kúrò láàrin yín; gbogbo Israẹli yóo gbọ́, wọn yóo sì bẹ̀rù.
22 “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ kan, tí ó jẹ́ pé ikú ni ìjìyà irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ẹ bá so ó kọ́ sórí igi,
23 òkú rẹ̀ kò gbọdọ̀ sun orí igi náà. Ẹ níláti sin ín ní ọjọ́ náà, nítorí ẹni ìfibú Ọlọrun ni ẹni tí a bá so kọ́ orí igi, ẹ kò gbọdọ̀ sọ ilẹ̀ yín tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín di aláìmọ́.