1 “Ní ọdún keje-keje ni kí ẹ máa ṣe ìdásílẹ̀.
2 Bí ẹ óo ṣe máa ṣe ìdásílẹ̀ náà nìyí: ẹnikẹ́ni tí aládùúgbò rẹ̀, tíí ṣe arakunrin rẹ̀, bá jẹ ní gbèsè kò ní gba ohun tí aládùúgbò rẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́, nítorí pé, a ti kéde ìdásílẹ̀ tíí ṣe ti OLUWA.
3 Bí ó bá jẹ́ pé àlejò ni ó jẹ ẹni náà ní gbèsè, olúwarẹ̀ lè gbà á, ṣugbọn ohunkohun tí ó bá jẹ́ tiyín, tí ó wà lọ́wọ́ arakunrin yín, ẹ kò gbọdọ̀ gbà á pada.
4 “Ṣugbọn kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo jẹ́ talaka, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín, ní ilẹ̀ tí ó fun yín láti gbà,
5 bí ẹ bá sá ti gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì farabalẹ̀, ti ẹ tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.
6 Nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Ẹ óo máa yá àwọn orílẹ̀-èdè ni nǹkan, ṣugbọn ẹ kò ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. Ẹ óo máa jọba lórí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ṣugbọn wọn kò ní jọba lórí yín.
7 “Bí ẹnìkan ninu yín, tí ó jẹ́ arakunrin yín, bá jẹ́ talaka, tí ó sì wà ninu ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ dijú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ háwọ́ sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka yìí.
8 Ẹ gbọdọ̀ lawọ́ sí i, kí ẹ sì yá a ní ohun tí ó tó láti tán gbogbo àìní rẹ̀, ohunkohun tí ó wù kí ó lè jẹ́.
9 Ẹ ṣọ́ra, kí èròkerò má baà gba ọkàn yín, kí ẹ wí pé, ọdún keje tíí ṣe ọdún ìdásílẹ̀ ti súnmọ́ tòsí, kí ojú yín sì le sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka, kí ẹ má sì fún un ní ohunkohun. Kí ó má baà ké pe OLUWA nítorí yín, kí ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ si yín lọ́rùn.
10 Ẹ fún un ní ohun tí ẹ bá fẹ́ fún un tọkàntọkàn, kì í ṣe pẹlu ìkùnsínú, nítorí pé, nítorí ìdí èyí ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín ati gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé.
11 Nítorí pé, talaka kò ní tán lórí ilẹ̀ yín, nítorí náà ni mo ṣe ń pàṣẹ fun yín pé kí ẹ lawọ́ sí arakunrin yín, ati sí talaka ati sí aláìní ní ilẹ̀ náà.
12 “Bí wọ́n bá ta arakunrin yín lẹ́rú fun yín, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, tí ó bá ti jẹ́ Heberu, ọdún mẹfa ni yóo fi sìn yín. Tí ó bá di ọdún keje, ẹ gbọdọ̀ dá a sílẹ̀, kí ó sì máa lọ.
13 Nígbà tí ẹ bá dá a sílẹ̀ pé kí ó máa lọ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ ní ọwọ́ òfo.
14 Ẹ gbọdọ̀ fún un ní ẹran ọ̀sìn lọpọlọpọ ati ọkà láti inú ibi ìpakà yín, ati ọtí waini. Bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe fún un tó.
15 Ẹ gbọdọ̀ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada; nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín lónìí.
16 “Ṣugbọn tí ó bá wí fun yín pé, òun kò ní jáde ninu ilé yín, nítorí pé ó fẹ́ràn ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín, nítorí pé ó dára fún un nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ yín,
17 ẹ mú ìlutí kan, kí ẹ fi lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn. Yóo sì jẹ́ ẹrukunrin yín títí lae. Bí ó bá sì jẹ́ obinrin ni, bákan náà ni kí ẹ ṣe fún un.
18 Má jẹ́ kí ó ni ọ́ lára láti dá a sílẹ̀ kí ó sì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé, ìdajì owó ọ̀yà alágbàṣe ni ó ti fi ń sìn ọ́, fún odidi ọdún mẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.
19 “Gbogbo àkọ́bí tí ẹran ọ̀sìn bá bí ninu agbo ẹran yín, tí ó bá jẹ́ akọ ni ẹ gbọdọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí ninu agbo mààlúù yín ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ rẹ́ irun àgbò tí ó jẹ́ àkọ́bí aguntan yín.
20 Níbikíbi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn, ni ẹ ti gbọdọ̀ máa jẹ wọ́n níwájú rẹ̀, ní ọdọọdún; ẹ̀yin ati gbogbo ilé yín.
21 Ṣugbọn bí ó bá ní àbààwọ́n kan, bóyá ó jẹ́ arọ ni, tabi afọ́jú, tabi ó ní àbààwọ́n kankan, ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín,
22 jíjẹ ni kí ẹ jẹ ẹ́ ní ààrin ìlú yín, ati àwọn tí wọ́n mọ́, ati àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ ni wọ́n lè jẹ ninu rẹ̀, bí ìgbà tí eniyan jẹ ẹran èsúó tabi àgbọ̀nrín ni.
23 Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ; dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.