Diutaronomi 28 BM

Ibukun fún Ìgbọràn

1 “Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ.

2 Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ.

3 “OLUWA yóo bukun ọ ní ààrin ìlú, yóo sì bukun oko rẹ.

4 “Yóo bukun àwọn ọmọ rẹ, ati èso ilẹ̀ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àwọn ọmọ mààlúù rẹ, ati àwọn ọmọ aguntan rẹ.

5 “OLUWA yóo fi ibukun rẹ̀ sí orí ọkà rẹ, ati oúnjẹ rẹ.

6 “Yóo bukun ọ nígbà tí o bá ń wọlé, yóo sì tún bukun ọ nígbà tí o bá ń jáde.

7 “Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ.

8 “OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ.

9 “OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

10 Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ.

11 OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ.

12 OLUWA yóo fún ọ ní ọpọlọpọ òjò ní àkókò rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra rẹ̀ lójú ọ̀run, yóo sì bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ìwọ ni o óo máa yá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, o kò sì ní tọrọ lọ́wọ́ wọn.

13 OLUWA yóo fi ọ́ ṣe orí, o kò ní di ìrù; òkè ni o óo máa lọ, o kò ní di ẹni ilẹ̀; bí o bá pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ, tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, tí o mú gbogbo wọn ṣẹ lẹ́sẹẹsẹ,

14 tí o kò bá yipada ninu àwọn òfin tí mo ṣe fún ọ lónìí, tí o kò sì sá tọ àwọn oriṣa lọ, láti máa bọ wọ́n.

Ìjìyà fún Àìgbọràn

15 “Ṣugbọn bí o kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o kò sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, bí mo ti fi lélẹ̀ fún ọ lónìí, gbogbo àwọn ègún wọnyi ni yóo ṣẹ sí orí rẹ tí yóo sì mọ́ ọ.

16 “Ègún ni fún ọ ní ààrin ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.

17 “Ègún ni fún ọkà rẹ ati oúnjẹ rẹ.

18 “Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, ati fún èso ilẹ̀ rẹ ati fún àwọn ọmọ mààlúù rẹ ati àwọn ọmọ aguntan rẹ.

19 “Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé, ègún sì ni fún ọ nígbà tí o bá jáde.

20 “Bí o bá ṣe ibi, tí o kọ OLUWA sílẹ̀, ninu gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé, èmi OLUWA yóo da ègún lé ọ lórí, n óo sì mú ìdàrúdàpọ̀ ati wahala bá ọ, títí tí o óo fi parun patapata, láìpẹ́, láìjìnnà.

21 OLUWA yóo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ọ títí tí yóo fi pa ọ́ run patapata, lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti gbà.

22 OLUWA yóo fi àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ṣe ọ́, ati ibà, ìgbóná ati ooru; yóo sì rán ọ̀gbẹlẹ̀, ọ̀dá, ati ìrẹ̀dànù sí ohun ọ̀gbìn rẹ, títí tí o óo fi parun.

23 Òjò kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.

24 Dípò òjò, eruku ni yóo máa dà bò ọ́ láti ojú ọ̀run, títí tí o óo fi parun patapata.

25 “OLUWA yóo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ ṣẹgun rẹ. Bí o bá jáde sí wọn ní ọ̀nà kan, OLUWA yóo tú ọ ká níwájú wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ yóo sì di ìyanu ati ẹ̀rù ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.

26 Òkú rẹ yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko tí ń káàkiri orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí óo lé wọn kúrò.

27 OLUWA yóo da irú oówo tí ó fi bá àwọn ará Ijipti jà bò ọ́, ati egbò, èkúkú ati ẹ̀yi, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wòsàn.

28 OLUWA yóo da wèrè, ìfọ́jú, ati ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bò ọ́.

29 O óo máa táràrà lọ́sàn-án gangan bí afọ́jú. Kò ní dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọn yóo máa ni ọ́ lára, wọn yóo sì máa jà ọ́ lólè nígbà gbogbo; kò sì ní sí ẹnìkan láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

30 “O óo fẹ́ iyawo sọ́nà, ẹlòmíràn ni yóo máa bá a lòpọ̀. O óo kọ́ ilé, o kò sì ní gbé inú rẹ̀. O óo gbin ọgbà àjàrà, o kò sì ní jẹ ninu èso rẹ̀.

31 Wọn óo máa pa akọ mààlúù rẹ lójú rẹ, o kò ní fẹnu kàn ninu rẹ̀. Wọn óo fi tipátipá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lọ lójú rẹ, wọn kò sì ní dá a pada fún ọ mọ́. Àwọn aguntan yín yóo di ti àwọn ọ̀tá yín, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn yín lọ́wọ́.

32 Àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin óo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Ẹ óo retí wọn títí, ẹ kò ní gbúròó wọn, kò sì ní sí ohunkohun tí ẹ lè ṣe sí i.

33 Orílẹ̀-èdè tí ẹ kò mọ̀ rí ni yóo jẹ ohun ọ̀gbìn yín ati gbogbo làálàá yín ní àjẹrun. Ìnilára ati ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹ óo máa rí nígbà gbogbo,

34 tóbẹ́ẹ̀ tí ohun tí ẹ óo máa fi ojú yín rí yóo yà yín ní wèrè.

35 OLUWA yóo da oówo burúkú bò yín lẹ́sẹ̀ ati lórúnkún, yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wò yín sàn. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín títí dé àtàrí yín kìkì oówo ni yóo jẹ́.

36 “OLUWA yóo lé ẹ̀yin ati ẹni tí ẹ bá fi jọba yín lọ sí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa tí wọ́n fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀.

37 Ẹ óo di ẹni ìríra, ẹni àmúpòwe ati ẹni ẹ̀sín, láàrin gbogbo àwọn eniyan, níbi tí OLUWA yóo le yín lọ.

38 “Ọpọlọpọ èso ni ẹ óo máa gbìn sinu oko yín, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ óo máa rí ká, nítorí eṣú ni yóo máa jẹ wọ́n.

39 Ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò ní rí èso rẹ̀ ká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní mu ninu ọtí rẹ̀, nítorí pé àwọn kòkòrò yóo ti jẹ ẹ́.

40 Gbogbo ilẹ̀ yín yóo kún fún igi olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí òróró fi pa ara, nítorí pé rírẹ̀ ni èso olifi yín yóo máa rẹ̀ dànù.

41 Ẹ óo bí ọpọlọpọ ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn wọn kò ní jẹ́ tiyín, nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kó lẹ́rú lọ.

42 Gbogbo igi yín ati gbogbo èso ilẹ̀ yín ni yóo di ti àwọn eṣú.

43 “Àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín yóo máa níláárí jù yín lọ, ọwọ́ wọn yóo máa ròkè, ṣugbọn ní tiyín, ẹ óo di ẹni ilẹ̀ patapata.

44 Ọwọ́ àlejò yín ni ẹ óo ti máa tọrọ nǹkan, àwọn kò sì ní tọrọ ohunkohun lọ́wọ́ yín. Àwọn ni wọn yóo jẹ́ orí fun yín, ẹ̀yin yóo sì jẹ́ ìrù fún wọn.

45 “Gbogbo ègún wọnyi ni yóo ṣẹ si yín lára, tí yóo sì lẹ̀ mọ́ yín pẹ́kípẹ́kí títí tí ẹ óo fi parun, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò pa òfin rẹ̀ mọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tí ó pa láṣẹ fun yín.

46 Àwọn ègún náà yóo wà lórí yín gẹ́gẹ́ bí àmì ati ohun ìyanu, ati lórí àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

47 Nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun bukun yín, ẹ kọ̀, ẹ kò sìn ín pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn.

48 Nítorí náà, ní ìhòòhò, pẹlu ebi ati òùngbẹ, ati àìní ni ẹ óo fi máa sin àwọn ọ̀tá tí OLUWA yóo rán si yín, yóo sì la àjàgà irin bọ̀ yín lọ́rùn títí tí yóo fi pa yín run.

49 OLUWA yóo gbé orílẹ̀-èdè kan, tí ẹ kò gbọ́ èdè wọn, dìde si yín láti òpin ayé; wọn óo yára bí àṣá.

50 Ojú gbogbo wọn óo pọ́n kankan, wọn kò ní ṣàánú ọmọde, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní bọ̀wọ̀ fún àgbà.

51 Wọn yóo jẹ àwọn ọmọ ẹran yín ati èso ilẹ̀ yín títí tí ẹ óo fi parun patapata. Wọn kò ní ṣẹ́ nǹkankan kù fun yín ninu ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín, àwọn ọmọ mààlúù tabi ọmọ aguntan yín; títí tí wọn yóo fi jẹ yín run.

52 Gbogbo ìlú ńláńlá yín ni wọn óo dó tì, títí tí gbogbo odi gíga tí ẹ gbójúlé, tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá yín po, yóo fi wó lulẹ̀, ní gbogbo ilẹ̀ yín. Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín ni wọn yóo dó tì.

53 “Ojú yóo pọn yín tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá yin bá dó tì yín, tí yóo fi jẹ́ pé àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ni ẹ óo máa pa jẹ.

54 Ọkunrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn ọkunrin yín, yóo di ahun sí arakunrin rẹ̀, ati sí iyawo rẹ̀ tí ó fẹ́ràn jùlọ, ati sí ọmọ rẹ̀ tí ó kù ú kù,

55 tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní fún ẹnikẹ́ni jẹ ninu ẹran ara ọmọ rẹ̀ tí ó bá ń jẹ ẹ́; nítorí pé kò sí nǹkankan tí ó kù fún un mọ́, ninu ìnira tí àwọn ọ̀tá yín yóo kó yín sí nígbà tí wọ́n ba dó ti àwọn ìlú yín.

56 Obinrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn obinrin yín, tí kò jẹ́ fi ẹsẹ̀ lásán tẹ ilẹ̀ nítorí àwọ̀ rẹ̀ tí ó tutù ati ìwà afínjú rẹ̀, yóo di ahun sí ọkọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin.

57 Yóo bímọ tán, yóo sì jẹ ibi ọmọ tí ó jáde lára rẹ̀ ní kọ̀rọ̀, yóo sì tún jẹ ọmọ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, nítorí pé kò sí ohun tí ó lè jẹ mọ́, nítorí àwọn ọ̀tá yín tí yóo dó ti àwọn ìlú yín.

58 “Bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò tẹ̀lé gbogbo òfin tí a kọ sinu ìwé yìí, pé kí ẹ máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó lẹ́rù, tí ó sì lógo,

59 OLUWA yóo mú ìpọ́njú ńlá bá ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, ìpọ́njú ńlá ati àìsàn burúkú, tí yóo wà lára yín fún ìgbà pípẹ́.

60 Gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n bà yín lẹ́rù, ni OLUWA yóo dà bò yín, tí yóo sì wà lára yín.

61 Àwọn àìsàn mìíràn ati ìpọ́njú tí wọn kò kọ sinu ìwé òfin yìí ni OLUWA yóo dà bò yín títí tí ẹ óo fi parun.

62 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹ kò ni kù ju díẹ̀ lọ mọ́, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.

63 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ dídùn inú OLUWA láti ṣe yín ní rere ati láti sọ yín di pupọ, bákan náà ni yóo jẹ́ dídùn inú rẹ̀ láti ba yín kanlẹ̀ kí ó sì pa yín run. OLUWA yóo le yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.

64 OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí.

65 Ara kò ní rọ̀ yín rárá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí ìdí jókòó. OLUWA yóo mú jìnnìjìnnì ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ba yín, yóo sì mú kí ojú yín di bàìbàì.

66 Ninu hílàhílo ni ẹ óo máa wà nígbà gbogbo, ninu ẹ̀rù ati ìpayà ni ẹ óo máa wà tọ̀sán-tòru.

67 Àwọn ohun tí ojú yín yóo máa rí yóo kó ìpayà ati ẹ̀rù ba yín, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ilẹ̀ bá ti ṣú, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti mọ́; bí ilẹ̀ bá sì ti tún mọ́, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti ṣú.

68 Ọkọ̀ ojú omi ni OLUWA yóo fi ko yín pada sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí mo ti ṣèlérí pé ẹ kò ní pada sí mọ́ lae. Nígbà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ óo fa ara yín kalẹ̀ fún títà gẹ́gẹ́ bí ẹrú, lọkunrin ati lobinrin, ṣugbọn ẹ kò ní rí ẹni rà yín.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34