1 Ó ní:“Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé.
2 Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò,àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn;kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì,bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára.
3 Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA,àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀.
4 “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín,gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́.Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe,ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.
5 Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i,ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́,nítorí àbùkù yín;ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí.
6 Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí,ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi?Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín,Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀.
7 “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́,ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá.Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín,Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín,wọn yóo sì sọ fun yín.
8 Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè,ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé,gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.
9 Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀,ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀.
10 “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn,níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn.Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn,Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀.
11 Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká,láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò,tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọntí wọ́n bá fẹ́ já bọ́,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli.
12 OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀,láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan.
13 “Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé,ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ.Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta,ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta.
14 Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn,ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn,ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò,ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́,ati ọkà tí ó dára jùlọ,ati ọpọlọpọ ọtí waini.
15 “Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán,ẹ wá tàpá sí àṣẹ;ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára;ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín,ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín!
16 Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú;wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè.
17 Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú,Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí,tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí.
18 Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín,ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín.
19 “Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe,ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé, wọ́n mú un bínú.
20 Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn,n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.Nítorí olóríkunkun ni wọ́n,àwọn alaiṣootọ ọmọ!
21 Nítorí oriṣa lásánlàsàn,wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú;wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú.Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsànláti mu àwọn náà jowú,n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kanláti mú wọn bínú.
22 Nítorí iná ibinu mi ń jó,yóo sì jó títí dé isà òkú.Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun,tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
23 “ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn,n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn.
24 N óo fi ebi pa wọ́n ní àpakú,iná yóo jó wọn ní àjórun,n óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run.N óo jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú pa wọ́n jẹ,n óo sì jẹ́ kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán.
25 Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó,bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀.Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin,ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ.
26 Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri,kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́,
27 ti àwọn ọ̀tá wọn ni mo rò,nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn yóo máa wí kiri.Wọn yóo máa wí pé,“Àwa ni a ṣẹgun wọn,kìí ṣe OLUWA ló ṣe é rárá.” ’
28 “Nítorí pé aláìlérò orílẹ̀-èdè ni Israẹli,òye kò sì yé wọn rárá.
29 Bí ó bá ṣe pé wọ́n gbọ́n ni,tí òye sì yé wọn;wọn ì bá ti mọ̀ bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.
30 Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan?Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá?Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀,tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.
31 Nítorí pé, àwọn ọ̀tá wọn pàápàá mọ̀ pé,Ọlọrun, aláàbò Israẹli, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn oriṣa wọn.
32 Àwọn ọ̀tá wọn ti bàjẹ́ bíi Sodomu ati Gomora,wọ́n dàbí àjàrà tí ń so èso tí ó korò tí ó sì lóró.
33 Oró ejò ni ọtí wọn,àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani.
34 “Èmi OLUWA kò gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá wọn ṣe,ṣebí gbogbo rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ mi?
35 Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san,nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú.Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀,ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá.
36 Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀,nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́,ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn,tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn,kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.
37 Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé,‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà,ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin?
38 Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín,àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí?Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii,kí wọ́n sì dáàbò bò yín.
39 “ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé,èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun,kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi.Mo lè pa eniyan,mo sì lè sọ ọ́ di ààyè.Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́,mo sì lè wò ó sàn.Bí mo bá gbá eniyan mú,kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.
40 Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,mo fi ara mi búra.
41 Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,tí ó ń kọ yànrànyànràn,n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà.
42 Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,yóo sì mu àmuyó.Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,gbogbo wọn ni n óo pa.’
43 “Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA,gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀.Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà,yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”
44 Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni.
45 Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán,
46 ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ.
47 Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.”
48 OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé,
49 “Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli.
50 Orí òkè Nebo yìí ni o óo kú sí, bí Aaroni arakunrin rẹ ṣe kú lórí òkè Hori.
51 Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.
52 Nítorí náà, o óo fi ojú rí ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹsẹ̀ rẹ kò ní tẹ ilẹ̀ tí n ó fún àwọn eniyan Israẹli.”