Diutaronomi 8 BM

Ilẹ̀ Tí Ó Dára fún Ìní

1 “Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín.

2 Ẹ ranti gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti mú yín tọ̀ ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún yìí wá, láti tẹ orí yín ba; ó dán yín wò láti rí ọkàn yín, bóyá ẹ óo pa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ẹ kò ní pa á mọ́.

3 Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde.

4 Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ yín kò wú, fún odidi ogoji ọdún yìí.

5 Nítorí náà, ẹ mọ̀ ninu ara yín pé, gẹ́gẹ́ bí baba ti máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí ni OLUWA ń ba yín wí.

6 Nítorí náà, ẹ pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ ati bíbẹ̀rù rẹ̀.

7 Nítorí pé ilẹ̀ dáradára ni ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín ń mu yín lọ. Ó kún fún ọpọlọpọ adágún omi, ati orísun omi tí ó ń tú jáde ninu àwọn àfonífojì ati lára àwọn òkè.

8 Ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati baali, ọgbà àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́, ati igi pomegiranate, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin.

9 Ilẹ̀ tí ẹ óo ti máa jẹun, tí kò ní sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, níbi tí ẹ kò ní ṣe aláìní ohunkohun. Ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ jẹ́ irin, tí ẹ óo sì máa wa idẹ lára àwọn òkè rẹ̀.

10 Nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó, ẹ óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun yín fún ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín.

Ìkìlọ̀ nípa Gbígbàgbé OLUWA

11 “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, nípa àìpa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí,

12 kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó tán, tí ẹ ti kọ́ àwọn ilé dáradára, tí ẹ sì ń gbé inú wọn,

13 nígbà tí agbo mààlúù yín ati agbo aguntan yín bá pọ̀ sí i, tí wúrà ati fadaka yín náà sì pọ̀ sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní bá pọ̀ sí i,

14 kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú.

15 Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta,

16 ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn.

17 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín.

18 Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí.

19 Ṣugbọn, mò ń kìlọ̀ fun yín dáradára lónìí pé, bí ẹ bá gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń sá káàkiri tọ àwọn oriṣa lẹ́yìn, tí ẹ sì ń bọ wọ́n, píparun ni ẹ óo parun.

20 Gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo parun, nítorí pé ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34