Diutaronomi 4 BM

Mose Rọ Àwọn Ọmọ Israẹli Pé kí Wọn Máa Gbọ́ràn

1 Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ fi ọkàn sí àwọn ìlànà ati òfin tí mò ń kọ yín yìí, kí ẹ máa tẹ̀lé wọn, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ń mu yín lọ, kí ẹ sì lè gbà á.

2 Ẹ kò gbọdọ̀ fi kún òfin tí mo fun yín yìí, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀, kí ẹ lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun yín tí mo fun yín mọ́.

3 Ẹ̀yin náà ti fi ojú yín rí ohun tí OLUWA ṣe ní Baali Peori, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori run kúrò láàrin yín.

4 Ṣugbọn gbogbo ẹ̀yin tí ẹ di OLUWA Ọlọrun yín mú ṣinṣin ni ẹ wà láàyè títí di òní.

5 “Mo ti kọ yín ní ìlànà ati òfin gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún mi, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.

6 Ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn, wọn yóo sì sọ yín di ọlọ́gbọ́n ati olóye lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Orílẹ̀-èdè tí ó bá gbọ́ nípa àwọn ìlànà ati òfin wọnyi yóo wí pé, dájúdájú ọlọ́gbọ́n ati amòye eniyan ni yín.

7 “Ǹjẹ́, orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní oriṣa tí ó súnmọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun tií súnmọ́ wa nígbàkúùgbà tí a bá pè é?

8 Tabi orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní ìlànà ati òfin òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn tí mo gbé ka iwájú yín lónìí?

9 Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín,

10 gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’

11 “Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà.

12 Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́.

13 Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji.

14 OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.

Ìkìlọ̀ nípa Ìbọ̀rìṣà

15 “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu,

16 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ nípa yíyá ère fún ara yín, irú ère yòówù tí ó lè jẹ́; kì báà ṣe akọ tabi abo,

17 yálà àwòrán ẹrankokẹ́ranko tí ó wà ní orílẹ̀ ayé, tabi àwòrán ẹyẹkẹ́yẹ tí ń fò lójú ọ̀run,

18 kì báà ṣe àwòrán ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, tabi àwòrán ẹjakẹ́ja tí ń bẹ ninu omi.

19 Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá gbé ojú yín sókè sí ojú ọ̀run, tí ẹ bá rí oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ohun tí ó wà ní ojú ọ̀run, kí ọkàn yín má baà fà sí wọn, kí ẹ sì máa bọ àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fún gbogbo eniyan láyé.

20 Ọlọrun ti yọ yín kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó dàbí iná ìléru ńlá, ó ko yín jáde láti jẹ́ eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ lónìí.

21 Nítorí tiyín gan-an ni OLUWA ṣe bínú sí mi, tí ó sì fi ibinu búra pé, n kò ní kọjá sí òdìkejì Jọdani, n kò sì ní dé ilẹ̀ dáradára náà, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

22 Nítorí náà, mo níláti kú ní ìhín yìí, n kò gbọdọ̀ rékọjá sí òdìkejì Jọdani, ṣugbọn ẹ̀yin óo rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, ẹ óo sì gba ilẹ̀ dáradára náà.

23 Ẹ ṣọ́ra gidigidi, ẹ má gbàgbé majẹmu tí OLUWA Ọlọrun yín ba yín dá, ẹ má sì yá èrekére fún ara yín, ní àwòrán ohunkohun, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín lòdì sí i.

24 Nítorí iná tí ń jó ni run ni OLUWA Ọlọrun yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú sì ni.

25 “Nígbà tí ẹ bá ní ọmọ, ati àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà; bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀, nípa yíyá ère ní àwòrán ohunkohun, ati nípa ṣíṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ó lè mú un bínú,

26 ọ̀run ati ayé ń gbọ́ bí mo ti ń sọ yìí, pé ẹ óo parun patapata lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ gbà ní òdìkejì Jọdani. Ẹ kò ní pẹ́ níbẹ̀ rárá, ṣugbọn píparun ni ẹ óo parun.

27 OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí.

28 Ẹ óo sì máa bọ oriṣa tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni àwọn oriṣa wọnyi; wọn kò lè gbọ́ràn, tabi kí wọn ríran; wọn kò lè jẹun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbóòórùn.

29 Níbẹ̀ ni ẹ óo ti wá OLUWA Ọlọrun yín tí ẹ óo sì rí i, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹlu gbogbo ẹ̀mí yín.

30 Nígbà tí ẹ bá wà ninu ìpọ́njú, tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ń ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú, ẹ óo pada sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì gbọ́ tirẹ̀.

31 Nítorí pé, aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní já yín kulẹ̀, kò ní pa yín run, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbàgbé majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba ńlá yín dá.

32 “Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí.

33 Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kan gbọ́ kí oriṣa kan sọ̀rọ̀ láti ààrin gbùngbùn iná rí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì tún wà láàyè?

34 Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti?

35 OLUWA fi èyí hàn yín, kí ẹ lè mọ̀ pé òun ni Ọlọrun, ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi òun nìkan.

36 Ó mú kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, kí ó lè kọ yín; ó sì mú kí ẹ rí iná ńlá rẹ̀ láyé, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná náà.

37 Ìdí tí ó fi ṣe èyí ni pé, ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọmọ wọn; ó fi agbára ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ó sì wà pẹlu yín.

38 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ kúrò fun yín, kí ó baà lè ko yín wọlé kí ó sì fun yín ní ilẹ̀ wọn, kí ẹ sì jogún rẹ̀ bí ó ti wà lónìí.

39 Kí ẹ mọ̀ lónìí, kí ó sì da yín lójú pé, OLUWA ni Ọlọrun; kò sí ọlọrun mìíràn mọ́ ní ọ̀run ati ní ayé.

40 Nítorí náà, ẹ máa pa àwọn ìlànà ati òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ó lè dára fun yín, ati fún àwọn ọmọ yín; kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, títí lae.”

Àwọn Ìlú Ààbò Tí Ó Wà ní Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

41 Mose ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí ìlú ààbò,

42 kí ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan lè máa sálọ sibẹ; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n ní ìkùnsínú sí ara wọn tẹ́lẹ̀, lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí ó lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

43 Ó ya Beseri sọ́tọ̀ fún ẹ̀yà Reubẹni ninu aṣálẹ̀ láàrin ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ó ya Ramoti sọ́tọ̀ ní Gileadi, fún ẹ̀yà Gadi, ó sì ya Golani sọ́tọ̀ ní Baṣani, fún ẹ̀yà Manase.

Àlàyé lórí Òfin Ọlọrun Tí Mose Fẹ́ fún Wọn

44 Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin;

45 ó sì fi àwọn ìlànà ati àṣẹ lélẹ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti,

46 nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.

47 Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ ati ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani, Sihoni ati Ogu ni ọba àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani ní apá ìlà oòrùn

48 láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni),

49 ati gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani títí dé Òkun Araba, tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34