1 Ọ̀rọ̀ tí Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ninu aṣálẹ̀ nìyí, ní òdìkejì odò Jọdani, ní Araba tí ó kọjú sí Sufu, láàrin Parani, Tofeli, Labani, Haserotu ati Disahabu.
2 Ìrìn ọjọ́ mọkanla ni láti Horebu dé Kadeṣi Banea, tí eniyan bá gba ọ̀nà òkè Seiri.
3 Ní ọjọ́ kinni oṣù kọkanla, ní ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Ijipti, ni Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ohun tí OLUWA pàṣẹ fún un láti sọ fún wọn;
4 lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni; ati Ogu, ọba àwọn ará Baṣani, tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei.
5 Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn, ní ilẹ̀ Moabu, ni Mose ti ṣe àlàyé àwọn òfin wọnyi. Ó ní,
6 “OLUWA Ọlọrun wa sọ fún wa ní Horebu pé, a ti pẹ́ tó ní ẹsẹ̀ òkè náà.
7 Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.
8 Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ”
9 “Mo sọ fun yín nígbà náà pé, èmi nìkan kò ní lè máa ṣe àkóso yín.
10 OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ, lónìí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
11 Kí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín jẹ́ kí ẹ tún pọ̀ jù báyìí lọ lọ́nà ẹgbẹrun. Kí ó sì bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fun yín.
12 Báwo ni mo ṣe lè dá nìkan dàyàkọ ìnira yín ati ẹrù yín ati ìjà yín.
13 Mo ní kí ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n ní ìmọ̀ ati ìrírí láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì fi wọ́n ṣe olórí yín.
14 Ìdáhùn tí ẹ fún mi nígbà náà ni pé, ohun tí mo wí ni ó yẹ kí ẹ ṣe.
15 Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.
16 “Mo pàṣẹ fún àwọn adájọ́ yín nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn arakunrin yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo láàrin eniyan ati arakunrin rẹ̀, tabi àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
17 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’
18 Gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe nígbà náà ni mo pa láṣẹ fun yín.
19 “Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea.
20 Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa,
21 ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà.
22 “Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’
23 “Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
24 Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀.
25 Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa.
26 “Sibẹsibẹ, ẹ kọ̀, ẹ kò lọ, ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun yín pa fun yín.
27 Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run.
28 Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’
29 “Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín.
30 OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.
31 Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí.
32 Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́,
33 Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí.
34 “OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé,
35 ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín;
36 àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun.
37 OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀.
38 Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀.
39 Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn.
40 Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa.
41 “Nígbà náà, ẹ dá mi lóhùn, ẹ ní, ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA, nítorí náà, ẹ óo dìde, ẹ óo sì lọ jagun, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fun yín. Olukuluku yín bá múra láti jagun, gbogbo èrò yín nígbà náà ni pé kò ní ṣòro rárá láti ṣẹgun àwọn tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà.
42 “OLUWA wí fún mi pé, ‘Kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má gòkè lọ jagun, nítorí pé n kò ní bá wọn lọ; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn.’
43 Mo sọ ohun tí OLUWA wí fun yín, ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́. Ẹ ṣe oríkunkun sí àṣẹ OLUWA, ẹ sì lọ pẹlu ẹ̀mí ìgbéraga.
44 Àwọn ará Amori tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà bá jáde sí yín, wọ́n le yín bí oyin tíí lé ni, wọ́n sì pa yín ní ìpakúpa láti Seiri títí dé Horima.
45 Nígbà tí ẹ pada dé, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sọkún níwájú OLUWA, ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ tiyín, bẹ́ẹ̀ ni kò fetí sí ẹkún yín.
46 “Nítorí náà, gbogbo wa wà ní Kadeṣi fún ìgbà pípẹ́.