Diutaronomi 16 BM

Àjọ Ìrékọjá

1 “Ẹ máa ranti láti máa ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá fún OLUWA Ọlọrun yín ninu oṣù Abibu nítorí ninu oṣù Abibu ni ó kó yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, lálẹ́.

2 Ẹ níláti máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá sí OLUWA Ọlọrun yín láti inú agbo mààlúù yín, tabi agbo aguntan yín, níbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

3 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.

4 Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

5 “Ẹ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ àjọ ìrékọjá láàrin èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín.

6 Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

7 Bíbọ̀ ni kí ẹ bọ̀ ọ́, kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nígbà tí ó bá sì di òwúrọ̀ ẹ óo pada lọ sinu àgọ́ yín.

8 Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní ọjọ́ keje, ẹ óo pe àpèjọ tí ó ní ọ̀wọ̀, ẹ óo sì sin OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà.

Àjọ̀dún Ìkórè

9 “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e.

10 Nígbà náà, ẹ óo ṣe àsè àjọ ọ̀sẹ̀, tíí ṣe àjọ̀dún ìkórè fún OLUWA Ọlọrun yín; pẹlu ọrẹ àtinúwá. Ẹ óo mú ọrẹ náà wá bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín.

11 Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín.

12 Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà wọnyi.

Àjọ̀dún Àgọ́

13 “Ọjọ́ meje ni ẹ gbọdọ̀ máa fi se àsè àjọ̀dún àgọ́ nígbà tí ẹ bá kó ọkà yín jọ láti ibi ìpakà, tí ẹ kó ọtí waini yín jọ láti ibi ìfúntí.

14 Ẹ máa yọ̀, bí ẹ ti ń gbádùn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin, ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin ati àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, àwọn ọmọ Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà ní àwọn ìlú yín.

15 Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi se àsè yìí fún OLUWA Ọlọrun yín níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun gbogbo èso yín, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo láyọ̀ gidigidi.

16 “Ìgbà mẹta láàrin ọdún kan ni gbogbo àwọn ọkunrin yín yóo máa farahàn níwájú OLUWA níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun; àkókò àjọ̀dún burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati àkókò àjọ̀dún ìkórè, ati àkókò àjọ̀dún àgọ́. Wọn kò gbọdọ̀ farahàn níwájú OLUWA ní ọwọ́ òfo.

17 Olukuluku ọkunrin yóo mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí ó bá ti fẹ́ ati gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun un.

Ìlànà nípa Ẹjọ́ Dídá

18 “Ẹ yan àwọn adájọ́ ati àwọn olórí tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà yín, ní àwọn ìlú yín, wọn yóo sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn eniyan.

19 Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, ẹ kò sì gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀; nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ọlọ́gbọ́n lójú, a sì máa yí ẹjọ́ aláre pada sí ẹ̀bi.

20 Ẹ̀tọ́ nìkan ṣoṣo ni kí ẹ máa ṣe, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ sì lè jogún ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

21 “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin igikígi bí igi oriṣa Aṣera sí ẹ̀bá pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, nígbà tí ẹ bá ń kọ́ ọ.

22 Ẹ kò sì gbọdọ̀ ri òpó mọ́lẹ̀ kí ẹ máa bọ ọ́, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín kórìíra wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34