Diutaronomi 20 BM

Ọ̀rọ̀ nípa Ogun

1 “Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín.

2 Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé,

3 ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín.

4 Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’

5 “Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́.

6 Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀.

7 Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’

8 “Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’

9 Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun.

10 “Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn.

11 Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.

12 Ṣugbọn bí wọ́n bá kọ̀, tí àwọn náà dìde ogun si yín, ẹ dó ti ìlú náà.

13 Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi ìlú náà le yín lọ́wọ́, kí ẹ fi idà pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀.

14 Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín.

15 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín.

16 “Ṣugbọn gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín, gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ kò gbọdọ̀ dá ohun alààyè kan sí ninu wọn.

17 Rírun ni kí ẹ run gbogbo wọn patapata, gbogbo àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Kenaani, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi; gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti pa á láṣẹ.

18 Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín.

19 “Nígbà tí ẹ bá dó ti ìlú kan fún ìgbà pípẹ́, tí ẹ bá ń bá ìlú náà jagun tí ẹ fẹ́ gbà á, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ́ àwọn igi eléso wọn lulẹ̀ ní ìbẹ́kúbẹ̀ẹ́. Jíjẹ ni kí ẹ máa jẹ èso igi wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gé wọn lulẹ̀. Àbí eniyan ni igi inú igbó, tí ẹ óo fi máa gbé ogun tì í?

20 Àwọn igi tí ẹ bá mọ̀ pé èso wọn kìí ṣe jíjẹ nìkan ni kí ẹ máa gé, kí ẹ máa fi ṣe àtẹ̀gùn, tí ẹ fi lè wọ ìlú náà, títí tí ọwọ́ yín yóo fi tẹ̀ ẹ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34