Diutaronomi 3 BM

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Ogu Ọba

1 “Lẹ́yìn náà, a gbéra, a doríkọ ọ̀nà Baṣani. Ogu, ọba Baṣani, ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ṣígun wá pàdé wa ní Edirei.

2 Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’

3 “OLUWA Ọlọrun wa bá fi Ogu, ọba Baṣani, lé wa lọ́wọ́, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. A pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan rẹ̀.

4 A gba gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, kò sí ìlú kan tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn ninu gbogbo àwọn ìlú wọn. Gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta, gbogbo agbègbè Arigobu ati ìjọba Ogu ní Baṣani ni a gbà.

5 Wọ́n mọ odi gíga gíga yípo gbogbo àwọn ìlú ọ̀hún, olukuluku wọ́n sì ní odi tí ó ga ati ẹnubodè pẹlu ọ̀pá ìdábùú, láìka ọpọlọpọ àwọn ìlú kéékèèké tí kò ní odi.

6 A run gbogbo wọn patapata gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sí Sihoni, ọba Heṣiboni, tí a run gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ati ọkunrin, ati obinrin, ati ọmọde.

7 Ṣugbọn a kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati àwọn ohun tí a rí ninu ìlú wọn bí ìkógun.

8 “A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni.

9 (Herimoni Sirioni ni àwọn ará Sidoni ń pe òkè náà, ṣugbọn àwọn ará Amori ń pè é ní Seniri.)

10 A sì tún gba gbogbo àwọn ìlú wọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati gbogbo ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka ati Edirei, àwọn ìlú tí ó wà ninu ìjọba Ogu, ọba Baṣani.”

11 (Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.)

Àwọn Ẹ̀yà Tí Wọ́n Tẹ̀dó sí Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

12 “Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀.

13 Ìdajì tí ó kù lára ilẹ̀ àwọn ará Gileadi, ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Baṣani tíí ṣe ìjọba Ogu, ati gbogbo agbègbè Arigobu, ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase.”(Gbogbo ilẹ̀ Baṣani ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ àwọn Refaimu.

14 Jairi láti inú ẹ̀yà Manase ni ó gba gbogbo agbègbè Arigobu tí à ń pè ní Baṣani, títí dé etí ààlà ilẹ̀ àwọn Geṣuri, ati ti àwọn Maakati. Ó sọ àwọn ìlú náà ní orúkọ ara rẹ̀; ó pè wọ́n ní Hafoti Jairi. Orúkọ náà ni wọ́n ń jẹ́ títí di òní olónìí.)

15 Makiri, láti inú ẹ̀yà Manase ni mo fún ní ilẹ̀ Gileadi.

16 Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni;

17 ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn.

18 “Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín.

19 Ṣugbọn àwọn aya yín ati àwọn ọmọ yín kéékèèké ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ pé wọ́n ti di pupọ nisinsinyii) yóo wà ninu àwọn ìlú tí mo ti fun yín

20 títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’

21 “Mo sọ fún Joṣua nígbà náà pé; ‘Ṣé ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe sí àwọn ọba meji wọnyi? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA yóo ṣe sí ìjọba yòókù tí ẹ óo gbà.

22 Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn rárá, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín.’

Ọlọrun Kò Jẹ́ kí Mose Wọ Ilẹ̀ Kenaani

23 “Mo bẹ OLUWA nígbà náà, mo ní,

24 ‘OLUWA Ọlọrun, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi ati agbára rẹ han èmi iranṣẹ rẹ ni; nítorí pé, oriṣa wo ló wà, lọ́run tabi láyé yìí tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi tìrẹ?

25 Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’

26 “Ṣugbọn OLUWA bínú sí mi nítorí yín, kò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, ‘Ó tó gẹ́ẹ́, má ṣe bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.

27 Gun orí òkè Pisiga lọ, gbé ojú sókè, kí o sì wo apá ìwọ̀ oòrùn, ati apá àríwá, ati apá gúsù, ati apá ìlà oòrùn. Ojú ni o óo fi rí i, nítorí pé, o kò ní kọjá odò Jọdani yìí sí òdìkejì.

28 Ṣugbọn pàṣẹ fún Joṣua, mú un lọ́kàn le, kí o sì kì í láyà; nítorí pé, òun ni yóo ṣiwaju àwọn eniyan wọnyi lọ, tí wọn yóo fi gba ilẹ̀ tí o óo rí.’

29 “Nítorí náà a bá dúró sí àfonífojì, ní òdìkejì Betipeori.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34