Diutaronomi 11 BM

Títóbi OLUWA

1 “Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo ìkìlọ̀ ati ìlànà, ati ìdájọ́, ati òfin rẹ̀ nígbà gbogbo.

2 (Kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí mò ń sọ ni mò ń bá sọ̀rọ̀); nítorí náà, ẹ máa ṣe akiyesi ìtọ́ni OLUWA Ọlọrun yín, ati títóbi rẹ̀, ati agbára rẹ̀, ati ipá rẹ̀.

3 Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe ní ilẹ̀ Ijipti sí ọba Farao, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

4 Ẹ ranti ohun tí ó ṣe sí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ijipti ati sí àwọn ẹṣin wọn ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn; bí ó ti jẹ́ kí omi Òkun Pupa bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń le yín bọ̀, ati bí OLUWA ti pa wọ́n run títí di òní olónìí.

5 Ẹ ranti ohun gbogbo tí ó ṣe fun yín ninu aṣálẹ̀ títí tí ẹ fi dé ìhín;

6 ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli.

7 Ẹ ti fi ojú rí gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA ṣe.

Ibukun Ilẹ̀ Ìlérí náà

8 “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà.

9 Kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fún wọn ati àwọn arọmọdọmọ wọn. Ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó sì ní ẹ̀tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin.

10 Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́.

11 Ṣugbọn ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè ati àfonífojì. Láti ojú ọ̀run ni òjò ti ń rọ̀ sí i.

12 OLUWA Ọlọrun yín tìkararẹ̀ ni ó ń tọ́jú rẹ̀, tí ó sì ń mójútó o láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí dé òpin.

13 “Tí ẹ bá tẹ̀lé òfin mi tí mo fun yín lónìí, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn ati ẹ̀mí yín,

14 yóo rọ òjò sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ baà lè kórè ọkà, ọtí waini, ati òróró olifi yín.

15 Yóo mú kí koríko dàgbà ninu pápá fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ óo jẹ, ẹ óo sì yó.

16 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ̀tàn má baà wọ inú ọkàn yín, kí ẹ má baà yipada sí àwọn oriṣa, kí ẹ sì máa bọ wọ́n.

17 Kí inú má baà bí Ọlọrun si yín, kí o má baà mú kí òjò dáwọ́ dúró, kí ilẹ̀ yín má sì so èso mọ́; kí ẹ má baà parun kíákíá lórí ilẹ̀ tí OLUWA fun yín.

18 “Nítorí náà, ohun tí mo sọ fun yín yìí, ẹ pa á mọ́ sinu ọkàn yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín mejeeji.

19 Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde.

20 Ẹ kọ ọ́ sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín ati sí ara ẹnu ọ̀nà àbájáde ilé yín.

21 Kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun búra fún àwọn baba yín, pé òun yóo fún wọn títí lae, níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá wà lókè.

22 “Tí ẹ bá ṣọ́ra, tí ẹ sì pa gbogbo òfin tí mo fun yín mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,

23 OLUWA yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde fun yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ.

24 Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

25 Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.

26 “Ẹ wò ó, mo gbé ibukun ati ègún kalẹ̀ níwájú yín lónìí.

27 Ibukun ni fun yín bí ẹ bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí mo fun yín lónìí yìí.

28 Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí.

29 Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú yín dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ, tí ẹ óo sì gbà, ẹ kéde ibukun náà lórí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde ègún náà lórí òkè Ebali.

30 Òkè Gerisimu ati òkè Ebali wà ní òdìkejì Jọdani, ní ojú ọ̀nà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé Araba, ní òdìkejì Giligali, lẹ́bàá igi Oaku More.

31 Nítorí ẹ óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á tán, tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀,

32 ẹ ṣọ́ra, kí ẹ máa tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati òfin tí mo fi lélẹ̀ níwájú yín lónìí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34