2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo lé kúrò ti ń sin oriṣa wọn ni kí ẹ wó lulẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà lórí òkè ńlá, ati àwọn tí wọ̀n wà lórí àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ igi tútù.
3 Ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ fọ́ gbogbo òpó wọn, ẹ dáná sun àwọn ère oriṣa Aṣera wọn, ẹ gé gbogbo àwọn ère oriṣa wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò níbẹ̀.
4 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa sin OLUWA Ọlọrun yín káàkiri bí wọ́n ti ń ṣe.
5 Ṣugbọn ibi tí OLUWA bá yàn láti gbé ibùjókòó rẹ̀ kà láàrin gbogbo àwọn ẹ̀yà, ibẹ̀ ni kí ẹ máa lọ.
6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú gbogbo ẹbọ sísun yín, ati àwọn ẹbọ yòókù wá, ati ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA, ati àkọ́bí mààlúù yín, ati ti aguntan yín.
7 Ibẹ̀ ni ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín yóo ti jẹun níwájú OLUWA Ọlọrun yín, inú yín yóo sì dùn nítorí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín tí OLUWA ti fi ibukun sí.
8 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe bí a ti ń ṣe níbí lónìí, tí olukuluku ń ṣe èyí tí ó dára lójú ara rẹ̀.