25 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA.
26 Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ.
27 Kí ẹ rú ẹbọ sísun yín ati ẹran ati ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ yín sórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì jẹ ara ẹran rẹ̀.
28 Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.
29 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run níbi gbogbo tí ẹ bá lọ, tí ẹ bá bá wọn jagun tí ẹ gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé ibẹ̀;
30 ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà ṣìnà, lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti pa wọ́n run tán, kí ẹ má baà bèèrè pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ṣe ń bọ àwọn oriṣa wọn? Kí àwa náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀.’
31 Ẹ kò gbọdọ̀ sin OLUWA Ọlọrun yín bí wọn ti ń bọ àwọn oriṣa wọn nítorí oríṣìíríṣìí ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú OLUWA ni wọ́n máa ń ṣe. Wọn a máa fi àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn rúbọ sí oriṣa wọn.