Diutaronomi 14:21-27 BM

21 “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín.“Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀.

22 “Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún.

23 Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo.

24 Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ,

25 ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

26 Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín.

27 “Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin yín nítorí pé, wọn kò ní ìpín tabi ohun ìní láàrin yín.