16 Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’
17 Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀.
18 “Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀.
19 Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn;
20 kí ó má baà rò ninu ara rẹ̀ pé òun ga ju àwọn arakunrin òun lọ, kí ó má baà yipada sí ọ̀tún tabi sí òsì kúrò ninu òfin OLUWA, kí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ lè pẹ́ lórí oyè ní Israẹli.