4 OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi;
5 ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.
6 Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’
7 “Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.
8 “A bá kọjá lọ láàrin àwọn arakunrin wa, àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri, a ya ọ̀nà tí ó lọ láti Elati ati Esiongeberi sí Araba sílẹ̀. A yipada a sì gba ọ̀nà aṣálẹ̀ Moabu.
9 OLUWA sọ fún mi pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ da àwọn ará Moabu láàmú, tabi kí ẹ gbógun tì wọ́n; nítorí pé n kò fun yín ní ilẹ̀ wọn, nítorí pé mo ti fi ilẹ̀ Ari fún àwọn ọmọ Lọti gẹ́gẹ́ bí ohun ìní wọn.’ ”
10 (Ìran àwọn òmìrán kan tí à ń pè ní Emimu ní ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Wọ́n pọ̀, wọ́n sì lágbára. Wọ́n ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki.