Diutaronomi 22:20-26 BM

20 “Ṣugbọn bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan obinrin náà bá jẹ́ òtítọ́, pé wọn kò bá a nílé,

21 Wọn yóo fa obinrin náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, àwọn ọkunrin ìlú yóo sì sọ ọ́ ní òkúta pa, nítorí pé ó ti hu ìwà òmùgọ̀ ní Israẹli níti pé ó ṣe àgbèrè ní ilé baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.

22 “Bí ọwọ́ bá tẹ ọkunrin kan ní ibi tí ó ti ń bá iyawo oníyàwó lòpọ̀, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa àwọn mejeeji; ati ọkunrin ati obinrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.

23 “Bí ẹnìkan bá rí ọmọge kan, tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà láàrin ìlú, tí ó sì bá a lòpọ̀,

24 ẹ mú àwọn mejeeji jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa. Ẹ̀ṣẹ̀ ti obinrin ni pé, nígbà tí wọ́n kì í mọ́lẹ̀ láàrin ìlú, kò pariwo kí aládùúgbò gbọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ti ọkunrin ni pé, ó ba àfẹ́sọ́nà arakunrin rẹ̀ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.

25 “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ninu igbó ni ọkunrin kan ti ki ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹnìkan mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, ọkunrin nìkan ni kí wọ́n pa.

26 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun sí ọmọbinrin náà, kò jẹ̀bi ikú rárá, nítorí ọ̀rọ̀ náà dàbí pé kí ọkunrin kan pàdé aládùúgbò rẹ̀ kan lójú ọ̀nà, kí ó sì lù ú pa.