Diutaronomi 22:3-9 BM

3 Bákan náà ni ẹ níláti ṣe, tí ó bá jẹ́ pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni ó sọnù, tabi aṣọ rẹ̀, tabi ohunkohun tí ó bá jẹ́ ti arakunrin yín, tí ó bá sọnù tí ẹ sì rí i. Ẹ kò gbọdọ̀ mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i.

4 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù arakunrin yín, tí ó wó lulẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, kí ẹ sì mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. Ẹ níláti ràn án lọ́wọ́ láti gbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù rẹ̀ dìde.

5 “Obinrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti ọkunrin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkunrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti obinrin nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìríra ni ó jẹ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.

6 “Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn.

7 Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé.

8 “Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú.

9 “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sáàrin àwọn àjàrà tí ẹ bá gbìn sinu ọgbà àjàrà yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àjàrà náà, ati ohun tí ẹ gbìn sáàrin rẹ̀ yóo di ti ibi mímọ́.