Diutaronomi 32:36-42 BM

36 Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀,nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́,ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn,tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn,kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.

37 Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé,‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà,ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin?

38 Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín,àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí?Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii,kí wọ́n sì dáàbò bò yín.

39 “ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé,èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun,kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi.Mo lè pa eniyan,mo sì lè sọ ọ́ di ààyè.Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́,mo sì lè wò ó sàn.Bí mo bá gbá eniyan mú,kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.

40 Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,mo fi ara mi búra.

41 Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,tí ó ń kọ yànrànyànràn,n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà.

42 Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,yóo sì mu àmuyó.Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,gbogbo wọn ni n óo pa.’