40 Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,mo fi ara mi búra.
41 Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,tí ó ń kọ yànrànyànràn,n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà.
42 Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,yóo sì mu àmuyó.Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,gbogbo wọn ni n óo pa.’
43 “Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA,gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀.Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà,yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”
44 Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni.
45 Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán,
46 ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ.