11 OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn,sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ,Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn,tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.”
12 Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé:“Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò,OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo,ó sì ń gbé ààrin wọn.”
13 Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé:“Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá.
14 Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà.
15 Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára,kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké.
16 Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára,pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó.Kí ó wá sórí Josẹfu,àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀.
17 Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù,Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára,tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu,ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”