13 Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé:“Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá.
14 Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà.
15 Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára,kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké.
16 Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára,pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó.Kí ó wá sórí Josẹfu,àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀.
17 Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù,Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára,tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu,ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”
18 Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní:“Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni,sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari.
19 Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè,wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀.Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun,ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.”