26 ọ̀run ati ayé ń gbọ́ bí mo ti ń sọ yìí, pé ẹ óo parun patapata lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ gbà ní òdìkejì Jọdani. Ẹ kò ní pẹ́ níbẹ̀ rárá, ṣugbọn píparun ni ẹ óo parun.
27 OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí.
28 Ẹ óo sì máa bọ oriṣa tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni àwọn oriṣa wọnyi; wọn kò lè gbọ́ràn, tabi kí wọn ríran; wọn kò lè jẹun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbóòórùn.
29 Níbẹ̀ ni ẹ óo ti wá OLUWA Ọlọrun yín tí ẹ óo sì rí i, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹlu gbogbo ẹ̀mí yín.
30 Nígbà tí ẹ bá wà ninu ìpọ́njú, tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ń ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú, ẹ óo pada sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì gbọ́ tirẹ̀.
31 Nítorí pé, aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní já yín kulẹ̀, kò ní pa yín run, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbàgbé majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba ńlá yín dá.
32 “Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí.