24 wọ́n ní, ‘OLUWA Ọlọrun wa ti fi títóbi ati ògo rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná. Lónìí ni a rí i tí Ọlọrun bá eniyan sọ̀rọ̀, tí olúwarẹ̀ sì tún wà láàyè.
25 Nítorí náà, kí ló dé tí a óo fi kú? Nítorí pé, iná ńlá yìí yóo jó wa run; bí a bá tún gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa sí i, a óo kú.
26 Nítorí pé ninu gbogbo ẹ̀dá alààyè, ta ni ó tíì gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun alààyè rí láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ yìí, tí ó sì wà láàyè?
27 Ìwọ Mose, súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yóo sọ, kí o wá sọ fún wa, a óo sì ṣe é.’
28 “OLUWA gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ̀ ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mo gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi bá ọ sọ; gbogbo ohun tí wọ́n sọ pátá ni ó dára.
29 Yóo ti dára tó, bí wọ́n bá ní irú ẹ̀mí yìí nígbà gbogbo, kí wọ́n bẹ̀rù mi, kí wọ́n sì pa gbogbo òfin mi mọ́, kí ó lè dára fún wọn, ati fún àwọn ọmọ wọn títí lae.
30 Lọ sọ fún wọn pé, kí wọ́n pada sinu àgọ́ wọn.