3 Kì í ṣe àwọn baba wa ni OLUWA bá dá majẹmu yìí, ṣugbọn àwa gan-an tí a wà láàyè níhìn-ín lónìí ni ó bá dá majẹmu náà.
4 OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ lojukooju lórí òkè ní ààrin iná.
5 Èmi ni mo dúró láàrin ẹ̀yin ati OLUWA nígbà náà, tí mo sì sọ ohun tí OLUWA wí fun yín; nítorí ẹ̀rù iná náà ń bà yín, ẹ kò sì gun òkè náà lọ.“OLUWA ní,
6 ‘Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà:
7 “ ‘O kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, èmi OLUWA ni kí o máa sìn.
8 “ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.
9 O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi.