Diutaronomi 5:9-15 BM

9 O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi.

10 Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi, tí kì í yẹ̀, hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé òfin mi.

11 “ ‘O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán; nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi.

12 “ ‘Ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀, kí o sì ṣe é ní ọjọ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pàṣẹ fún ọ.

13 Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe gbogbo làálàá ati iṣẹ́ rẹ;

14 ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA Ọlọrun rẹ. Ní ọjọ́ náà, o kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati àwọn ọmọ rẹ obinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ, ati mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àlejò tí ń gbé ilẹ̀ rẹ; kí iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin rẹ lè sinmi bí ìwọ náà ti sinmi.

15 Ranti pé, ìwọ pàápàá ti jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti rí, ati pé OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó fi agbára rẹ̀ mú ọ jáde. Nítorí náà ni OLUWA Ọlọrun rẹ fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀.