6 Ẹ fi àṣẹ tí mo pa fun yín lónìí sọ́kàn,
7 kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára. Ẹ máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín, ati nígbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati nígbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀, ati nígbà tí ẹ bá dìde.
8 Ẹ so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín.
9 Ẹ kọ wọ́n sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín, ati sí ara ẹnu ọ̀nà ìta ilé yín.
10 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mu yín wọ ilẹ̀ tí ó búra fún Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba yín, pé òun yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n dára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ tẹ̀ wọ́n dó,
11 ati àwọn ilé tí ó kún fún àwọn nǹkan dáradára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ kó wọn sibẹ, ati kànga omi, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbẹ́ ẹ, ati àwọn ọgbà àjàrà ati igi olifi tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn ín. Nígbà tí ẹ bá jẹ, tí ẹ yó tán,
12 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà gbàgbé OLUWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti jẹ́ ẹrú.